Poems are products of word artistry. The talent of poem writing is not given to everyone. Hence people seek out already written love poems to recite to their lovers. Not bad…
In this article, we will look at 6 different Yoruba Love poems that you can try to recite to your husband, wife, girlfriend or boyfriend. The tonal marks were used for the words heavily to guide you in pronunciation.
More Yoruba Love poems will be added to this list over time so you can come here for updates in the future. Translations will also be added soon.
Poem 1. By Yusuf Gemini
Title: Ìfẹ tí ò ṣeé f’owó rà
Olólùfẹ́ mi o,
Owó kán iyebíye kò lè ràá ni ọja Akẹsán, ìfẹ tí mo ní sí ọ…
Olólùfẹ́ mi, ọmọ ẹdan ti n kọ ilé igi fún àwòkọ…
Wòó olólùfẹ́,
Ẹnu dùn-ún rò ẹ̀fọ́, agada owó ṣeé bẹ igi l’oko
Tí ń bá ni oókan àyà rẹ ni ìtànná ògo ń bẹ, má ṣe ròó lẹ́ẹ̀mejì oo!
Poem 2 by Yusuf Gemini
Title: Ojú ń ti ọbẹ inú àwo
Ọmọge mi oo!
Ọmọ àgbà ọ̀jé tí ń ya oòrùn
Iwọ ni al’oyin lóorun ti n pàṣẹ ọrọ f’ẹyin mi letido
Ọrọ ẹnu rẹ a sì máa ṣe yìnyìn bi ìrì àsìkò ọyẹ́
Ìfẹ mi ooo
Iwọ l’ọmọ atapẹtẹ sí’nú omi
Ọmọ a gbe iyán pupa fún àlejò pupa
Ojú ń tì mí, ojú n tí àlejò mí
Ojú n ti iyán, ojú n ti ọbẹ inú àwo!
Poem 3 by Yusuf Gemini
Title: Adúmáadán
Adúmáadán mi
Iwọ l’ará ilé ọ̀kín ti ń fọùn bi ènìyàn
Iwọ ni o mu omi tẹrẹrẹ ti n gba agbára lọwọ aṣebi
T’ẹni kan ba wi fun ẹ pe ifẹ wa ò gbóná
Má ṣe dá wọn loun o. Ìfẹ wa gbóná, ọ n gbóná fẹlifẹli bíi amala tó jiná.
Poem 4 by Yusuf Gemini
Title: Ade mi
Olówó orí mi, ade mí
Iwọ nikan l’odòdó ti ń bẹ l’agbàlá mi
Iwọ ni òdòdó ẹlẹ́rìn dòdò ti o jẹ ki n jẹ dòdò pẹlu awọn alái-l’ódodo
Wòó bi n ba fi odó gún iyán fún ọ, n kò ní rí ẹmọ níbẹ
Ọkọ mi, ìfẹ tó wà láàrin wa kò leè parẹ láíláí
Poem 5 by Yusuf Gemini
Title: Owo o leè raa
Oyin ayé mi, ìfẹ ọkàn mi, tèmi nikan ṣoṣo
Ìfẹ mi fún ọ kó ṣeé fi owó ẹyọ ra
Ikoko wa pẹlu kún fún omi afowuro pọnKo sí koko kankan lagbala ife wa
Ọrẹ ati ololufe l’ẹmi ati ore máa máa jẹ titi di ọjọ ogbó.
Eedumare ti ba wa f’aṣẹ síi.
Poem 6 by Yusuf Gemini
Title: Ododo mi
Olo mi, ododo mi, idunnu ayé mi
Ododo l’eyi ti mofe sọ fún é yìí o, kò sí efe nibe
Ife mi sí ọ afi bíi tefin òwú
Ani iwọ ni ododo elerin dodo ti n kọ do-re-mi-do-do-mi-re lookan aya mi.
Special thanks to Yusuf Gemini who is a Yoruba young Poet and Akéwì for allowing me to use the wordings of his past love poem performances in this article. You can check him on Twitter at @Yorubagemini HERE! Or check out his collection of Yoruba love Poems on YouTube at Yoruba Gemini.
AMAZING!!! IM BLOWN AWAY!!!
Its my sweethearts birthday, I was looking for something special and I stumbled on this page! Bookmarked on MY home page!!!
Y’all doing an awesome job here!
for me, it’s like share and repost!
5 ***** STAR!
Wawu. Thank you Gideon. Thank you for your words of appreciation. 🙏🏾 Ẹ ṣeun.
Wow, I love this, I like to know how I can also submit poems for readers, I love poetry a lot, especially African traditional poetry. I have written about 20 myself. Pls contact me via my email; navillegary@gmail.com ,thanks
Hello Olamide. If you want your Yoruba poems published, simply send me a mail at moyinolawoye@gmail.com. I will add you as an author on the blog. And you can start publishing your poems.